Yoruba Hymn APA 91 - Ojo ati akoko nlo
APA 91
1. Ojo ati akoko nlo
Nwon nsun wa s’ et i ’boji;
Awa fere dubule na,
Ninu iho ’busun wa.
2. Jesu, ’wo Olurapada
Ji okan t’ o ku s’ ese:
Ji gbogbo okan ti ntogbe,
Lati yan ipa iye.
3. Bi akoko ti nsunmole,
Je k’ a ro ’bi ti a nlo;
Bi lati r’ ayo ailopin,
Tabi egbe ailopin.
4. Aiye wan lo !
Iku de tan.
Jesu, so wa
Tit’ O fi de.
K’ a ba O gbe
K’ a ba O ku,
K’ a ba O joba titi lailai.
5. Aiye wa nkoja b’ ojiji
O s info lo bi ’kuku;
Fun gbogbo odun t’ o koja
Dariji wa, mu wa gbon.
6. Ko wa lati ka ojo wa,
Lati ba ese wa ja;
K’ a ma sare, k’ a ma togbe
Tit’ a o fi ri ’simi.
7. Gbogbo wa fere duro na
Niwaju ite ’dajo;
Jesu ’wo t’ o segun iku
Fi wa s’ apa otun Re.
8. Aiye wan lo !
Iku de tan :
Olugbala !
Jo pa wa mo.
K’ a ba O gbe,
K’ a ba O ku,
K’ a ba O joba titi lailai. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 91 - Ojo ati akoko nlo. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.