Yoruba Hymn APA 533 - Olorun, lat’ oro d’ ale
APA 533
1. Olorun, lat’ oro d’ ale,
Wakati wo l’ o dun pupo,
B’ eyi t’o pe mi wado Re
Fun adura?
2. Ibukun n’ itura oro;
Ibukun si l’oju ale;
Gbati mo f’ adura goke
Kuro laiye!
3. ’Gbana ’mole kan mo si mi,
O dan ju ’mole orun lo;
Iri ’bukun t’ aiye ko mo,
T’ odo Re wa.
4. Gbana l’ agbara mi dotun,
Gbana l’ a f’ ese mi ji mi,
Gbana l’o f’ ireti orun
M’ ara mi ya.
5. Enu ko le so ibukun
Ti mo nri f’ aini mi gbogbo;
Agbara, itunu, ati
Alafia.
6. Eru at’ iyemeji tan,
Okan mi f’orun se ile;
Omije ’ronupiwada
L’ a nu kuro.
7. Titi ngo de ’le ’bukun na,
Ko s’ anfani t’o le dun, bi
Ki nma tu okan mi fun O
Nin’ adura! Amin.
Yoruba Hymn APA 533 - Olorun, lat’ oro d’ ale
This is Yoruba Anglican hymns, APA 533- Olorun, lat’ oro d’ ale. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals