Yoruba Hymn APA 480 - Jesu t’ o wa l’ oke orun
APA 480
1. Jesu t’ o wa l’ oke orun,
Sokale d’ enia, o ku;
Ninu Bibeli l’ a le ri,
Bi On iti ma se rere.
2. O nkiri, o sin se rere,
O nla ’ju awon afoju;
Opo awon t’ o si yaro,
O sanu won, o si wo won.
3. Ju wonni lo, o wi fun won,
Ohun wonni t’ Olorun fe;
O si se enit’ o tutu,
Yio si gbo t’ awon ewe.
4. Sugbon iku t’ o ku buru,
A fi ko ’ri agbelebu;
Owo rere t’ o se nkan yi,
Nwon kan mo ’gi agbelebu.
5. O mo b’ enia ti buru,
O mo b’ iya ese ti ri;
Ninu anu Jesu wipe,
On o gba iya ese je.
6. Be l’ o ku nitori yin a,
O d’ enia, k’o ba le ku;
Bibeli ni, o t’ orun wa,
K’ o le dari ese ji ni.
7. Olorun o si f’ese ji
Awon t’o ronupiwada;
Je k’a ji kutu w’oju Re,
K’a si gba ekun ore Re. Amin.
Yoruba Hymn APA 480 - Jesu t’ o wa l’ oke orun
This is Yoruba Anglican hymns, APA 480- Jesu t’ o wa l’ oke orun . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals