Yoruba Hymn APA 449 - Balogun! Olugbala wa

Yoruba Hymn APA 449 - Balogun! Olugbala wa

Yoruba Hymn  APA 449 - Balogun! Olugbala wa

APA 449

 1. Balogun! Olugbala wa,

 Gb’ omo wonyi t’a bun O;

 Se won ye fun ise Tire,

 Arole iye wonyi.


2. Arewa Baba wa orun,

 Mu k’ awon wonyi jo O

 N’nu aworan Tire papa,

 Lo won s’ agbala oke.


3. Se won l’ agannigan mimo,

 Omo-ogun t’o lera;

 Ki nwon fo itegun Esu,

 Ki nwon si segun aiye.


4. K’ oro Re dabi oguna,

 L’ enu awon omo Re;

 Ti y’o jo ese l’ ajorun,

 K’ ara ba le da sasa.


5. Pa won mo fun ’se ogo Re,

 Ki nwon wa lailabawon;

 Ko won lati r’ agbelebu,

 Lojojumo aiye won.


6. Bukun ’lana igbala yi,

 Fun ire omo wonyi;

 Gba won, to won, si ma so won,

 Nikehin gb’ okan won la. Amin.



Yoruba Hymn  APA 449 - Balogun! Olugbala wa

This is Yoruba Anglican hymns, APA 449- Balogun! Olugbala wa. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals


إرسال تعليق (0)
أحدث أقدم