Yoruba Hymn APA 429 - Wo orison ohun rere
APA 429
1. ‘Wo orison ohun rere
Awa fe se ‘fe re;
Ohun wo l’ a le fi fun O,
Oba gbogbo aiye?
2. L’ aiye yi, ‘Wo ni otosi,
T’ o je enia Re:
Oruko won n’ Iwo njewo
Niwaju Baba Re.
3. ‘Gba nwon ba nke n’ inira won,
Ohun Re l’ awa ngbo;
‘Gba ba si nse itoju won,
Awa nse ‘toju Re.
4. Jesu, ma sai gba ore wa,
Si f’ ibukun Re si;
Ma f’ ibukun Re s’ ebun wa,
Fun awon t’ a nfi fun.
5. Fun Baba, Omo at’ Emi,
Olorun ti a nsin;
Ni ki a ma fi ogo fun,
Titi aiyeraiye. Amin.
Yoruba Hymn APA 429 - Wo orison ohun rere
This is Yoruba Anglican hymns, APA 429- Olori Ijo t’ orun . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals