Yoruba Hymn APA 427 - Oluwa orun on aiye

Yoruba Hymn APA 427 - Oluwa orun on aiye

Yoruba Hymn  APA 427 - Oluwa orun on aiye

APA 427

 1. Oluwa orun on aiye,

 ‘Wo n’ iyin at’ ope ye fun;

 Bawo l’ a ba ti fe O to,

 Onibu ore?


2. Orun ti nran, at’ afefe,

 Gbogbo eweko nso ‘fe Re;

 ‘Wo l’ O nmu irugbin dara,

 Onibu ore


3. Fun ara lile wa gbogbo,

 Fun gbogbo ibukun aiye,

 Awa yin O, a si dupe,

 Onibu ore


4. O ko du wa li Omo Re,

 O fi fun aiye ese wa,

 O si f’ebun gbogbo pelu,

 Onibu ore


5. O fun wa l’ Emi Mimo Re,

 Emi iye at’ agbara,

 O rojo ekun bukun Re

 Le wa lori.


6. Fun idariji ese wa,

 Ati fun ireti orun,

 Kil’ ohun t’ a ba fi fun O?

 Onibu ore.


7. Owo ti a nna, ofo ni,

 Sugbon eyi t’ a fi fun O,

 O je isura tit’ aiye,

 Onibu ore.


8. Ohun t’ a bun O, Oluwa,

 ‘Wo o sa nle pada fun wa;

 Layo l’a o ta O lore,

 Onibu ore.


9. Ni odo Re lati san wa,

 Olorun Olodumare;

 Jeki k’ a le ba O gbe titi,

 Onibu Ore. Amin.



Yoruba Hymn  APA 427 - Oluwa orun on aiye

This is Yoruba Anglican hymns, APA 427- Oluwa orun on aiye . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

إرسال تعليق (0)
أحدث أقدم