Yoruba Hymn APA 421 - Gbo, okan mi, bi Angeli ti nkorin

Yoruba Hymn APA 421 - Gbo, okan mi, bi Angeli ti nkorin

Yoruba Hymn  APA 421 - Gbo, okan mi, bi Angeli ti nkorin

APA 421

 1. Gbo, okan mi, bi Angeli ti nkorin,

 Yika orun ati yika aiye;

 E gbo bi oro orin won ti dun to!

 Ti nso gbati ese ki y’o si mo:

 Angeli Jesu, angel ’mole,

 Nwon nkorin ayo pade ero l’ona.

 

2. B’a si tin lo, be l’a si ngbo orin won,

 Wa, alare, Jesu l’o ni k’e wa;

 L’okunkun ni a ngbo orin didun won,

 Ohun orin won ni nfonahan wa.

 Angeli Jesu, &c.

 

3. Ohun Jesu ni a ngbo orin won,

 Ohun na ndun b’agogo y’aiye ka,

 Egbegberun awon t’o gbo ni si mbo:

 Mu won w’odo Re, Olugbala wa.

 Angeli Jesu, &c.

 

4. Isimi de, bi wahala tile po,

 Ile y’o mo, lehin okun aiye;

 Irin ajo pari f’awon alare,

 Nwon o d’orun, ’bi ’simi nikehin:

 Angeli Jesu, &c.


5. Ma korin nso, enyin Angeli rere,

 E ma korin didun k’a ba ma gbo;

 Tit’ ao fi nu omije oju wa nu:

 Ti a o si ma yo titi lailai:

 Angeli Jesu, angel ’mole,

 Nwon nkorin ayo pade ero l’ona. Amin.



Yoruba Hymn  APA 421 - Gbo, okan mi, bi Angeli ti nkorin

This is Yoruba Anglican hymns, APA 421- Gbo, okan mi, bi Angeli ti nkorin . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

إرسال تعليق (0)
أحدث أقدم