Yoruba Hymn APA 417 - Wa k’a da m’ awon ore wa
APA 417
1. Wa k’a da m’ awon ore wa,
Ti nwon ti jere na;
N’ ife k’a f’ okan ba won lo
Sode orun lohun.
2. K’awon t’aiye d’orin won mo,
T’ awon t’o lo s’ogo;
Awa l’aiye, awon l’orun,
Okan ni gbogbo wa.
3. Idile kan n’nu Krsit ni wa.
Ajo kan l’a si je;
Isan omi kan l’ o ya wa,
Isan omi iku.
4. Egbe ogun kan t’ Olorun,
Ase Re l’ a sin se;
Apakan ti wodo na ja,
Apakan nwo lowo!
5. Emi wa fere dapo na,
Y’o gb’ Ade bi ti won;
Ao yo s’ami Balogun wa,
Lati gbo ipe Re.
6. Jesu, so wa, s’amona wa,
Gbat’ oniko ba de;
Oluwa, pin omi meji,
Mu wa gunle l’ayo. Amin.
Yoruba Hymn APA 417 - Wa k’a da m’ awon ore wa
This is Yoruba Anglican hymns, APA 417- Wa k’a da m’ awon ore wa . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals