Yoruba Hymn APA 395 - Ko mi Oluwa, bi a ti
APA 395
1. Ko mi Oluwa, bi a ti
Je gbohungbohun oro Re;
B’ o ti wa mi, je k’ emi wa
Awon omo Re t’ o ti nu.
2. To mi Oluwa, kin le to
Awon asako si ona;
Bo mi Oluwa, kin le fi
Manna Re b’ awon t’ ebi npa.
3. Fun mi l’ agbara; fie se
Mi mule lori apata;
Kin le na owo igbala
S’ awon t’ o nri sinu ese.
4. Ko mi Oluwa, kin le fi
Eko rere Re k’ elomi;
F’ iye f’ oro mi, ko le fo
De ikoko gbogbo okan.
5. F’ isimi ’didun Re fun mi,
Fi kun mi li opolopo;
Ki ero ati oro mi
Kun fun ife at’ iyin Re.
6. Jesu, fi ekun Re kun mi,
Fi kun mi li opolopo;
Ki ero ati oro mi
Kun fun ife at’ iyin Re.
7. Lo mi, Oluwa, an’ emi,
Bi o ti fe, nigbakugba;
Tit em’ o fi r’ oju Re
Ti ngo pin ninu ogo Re. Amin.
Yoruba Hymn APA 395 - Ko mi Oluwa, bi a ti
This is Yoruba Anglican hymns, APA 395- Ko mi Oluwa, bi a ti . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals