Yoruba Hymn APA 366 - Olusagutan y’o pese
APA 366
1. Olusagutan y’o pese,
Y’o fi papa tutu bo mi;
Owo re y’o mu ’ranwo wa,
Oju re y’o si ma so mi;
Y’o ma ba mi kiri losan,
Loru y’o ma dabobo mi.
2. Nigbati mo nrare kiri
Ninu isina l’ aginju,
O mu mi wa si petele,
O fie se mi le ona;
Nib’ odo tutu nsan pele,
Larin papa oko tutu.
3. Bi mo tile nrin koja lo
Ni afonifoji iku,
Emi ki o berukeru,
’Tori Iwo wa pelu mi;
Ogo at’ opa Re y’o mu
Mi la ojiji iku ja.
4. Lehin are ija lile,
’Wo te tabili kan fun mi;
Ire at’ anu ni mo nri,
Ago mi si nkunwosile:
’Wo fun mi n’ ireti orun,
Ibugbe aiyeraiye mi. Amin.
Yoruba Hymn APA 366 - Olusagutan y’o pese
This is Yoruba Anglican hymns, APA 366- Olusagutan y’o pese . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals