Yoruba Hymn APA 249 - Ile ewa wonni, b’ o ti dara to
APA 249
1. Ile ewa wonni, b’ o ti dara to!
Ibugbe Olorun, t’ oju ko ti ri;
Ta l’ o fe de ibe, lehin aiye yi?
Ta l’ o fe k’ a wo on ni aso funfun?
2. Awon wonni ni, t’ o ji nin’ orun won;
Awon t’ o ni ’gbagbo si nkan t’ a ko ri;
Awon t’ o k’ aniyan won l’ Olugbala,
Awon ti ko tiju agbelebu Krist.
3. Awon ti ko nani gbogbo nkan aiye
Awon t’ o le soto de oju iku,
Awon t’ o nrubo ife l’ ojojumo,
Awon t’ a f’ igbala Jesu ra pada.
4. Itiju ni fun nyin, Om’-ogun Jesu,
Enyin ara ilu ibugbe orun,
Kinla! e nfi fere at’ ilu sire,
’Gbat’ o ni k’e sise, t’o sip e, “E ja!”
5. B’ igbi omi aiye si ti nkolu wa,
Jesu Oba ogo, so si wa l’ eti,
Adun t’ o wa l’orun, ilu mino ni,
Nibi t’ isimi w alai ati lailai. Amin.
Yoruba Hymn APA 249 - Ile ewa wonni, b’ o ti dara to
This is Yoruba Anglican hymns, APA 249- Ile ewa wonni, b’ o ti dara to . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals