Yoruba Hymn APA 221 - Eyi l’ojo ajinde
APA 221
1. Eyi l’ojo ajinde,
K’aiye wi kakiri:
Irekoja didun ni,
T’Olorun Olore!
Lat’ inu iku s’iye,
Lat’aiye si orun,
Ni Kristi ti mu wa koja,
Pel’orin isegun.
2. Oluwa, we okan wa,
K’o ba le mo toto;
K’a ba le ri Oluwa
N’nu ’mole ajinde;
K’a si f’eti s’ohun Re,
Ti ndun l’ohun jeje,
Pe, “Alafia fun nyin.”
K’a nde, k’a si tele.
3. Enyin orun, bu s’ayo,
K’aiye bere orin;
Ki gbogbo aiye yika,
Dapo lati gberin,
Eda nla ati wewe,
E gbohun nyin soke,
Tori Kristi ti jinde,
Ayo wa ki y’o pin. Amin.
Yoruba Hymn APA 221 - Eyi l’ojo ajinde
This is Yoruba Anglican hymns, APA 221- Eyi l’ojo ajinde . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals