Yoruba Hymn APA 213 - N’ iwaiya ’jakadi, On nikan nja

Yoruba Hymn APA 213 - N’ iwaiya ’jakadi, On nikan nja

Yoruba Hymn  APA 213 - N’ iwaiya ’jakadi, On nikan nja

APA 213

 GETSEMANE


1. N’ iwaiya ’jakadi, On nikan nja,

 O nfe iranlowo, sugbon ko ri.


2. B’ osupa ti nwo lor’ oke Olif’,

 Adura tani ngoke loru yi?


3. Eje wo l’eyi ti nro bi ojo

 Lat’ okan Re wa, “Eni ’banuje?”


4. Irora aileso mbe loju Re,

 Ojiya ti mbebe, tan’ Iwo?


 ONA IKANU


1. Gbo b’ O ti mba o soro lokan re,

 “Omo ti mo ku fun, tele mi.


2. “Kin ma m’ ago ti Baba fun mi bi?

 ’Gbati mimu re je ’gbala re?


3. “A lu, a tuto si, a fi sefe,

 A na, a si de l’ ade egun.


4. “Mo nlo si Golgota, nibe ngo ku,

 ’Tor’ ife mi si O; Emi ni.”


 ORO MEJE LORI AGBELEBU.


1. A kan mo’gi esin, ko kerora,

 O r’eru ese wa, Tire ko.


2. ’Wo Orun mi, o le wo okun bi?

 Oro wo l’o nte| nu Re wa ni?


3. “Baba dariji won,” l’adura Re,

 Baba si gbo, bi ’ti ma gbo ri


4. Gbo bi ole ni ti ntoro anu,

 On se ’leri Paradise fun.


5. Ibatan at’ Ore rogba yika,

 Maria on Magdalen r’opin re.


6. Meji ninu won di tiyatomo;

 Okan t’oro Re ti so d’okan.


7. Okunkun bo ile, osan d’oru,

 Iseju koja b’odun pipo.


8. Gbo ’gbe ’rora lat’ inu okun na,

 “Baba, ’Wo ko mi sile, ese?


9. A! ikosile nla! iku egun!

Igbe kil’ eyi, “Ongbe ngbe mi”


10. Gbo, “O ti pari,” Ijakadi pin,

Iku at’ ipoku, a se won.


11. “Baba, gba emi mi,” l’o wi kehin,

 Krist’ Oluwa iye, O si ku.


 IKESI.


1. “OMo ’rora mi, ti mo f’ eje ra,

 Mo gba o low’ esu, f’ Olorun;


2. “Wa alare, wa f’ori l’ aiya mi;

 Sapamo sodo mi, k’o simi.


3. “Wa sodo Baba mi, wa l’ aiberu,

 Alagbawi re, wa nitosi.


4. “Wa, mu ninu ore-ofe Emi:

 Emi ni ini re, ’Wo t’emi.”


 IDAHUN


1. Mo f’ ara mi fun O, Oluwa mi,

 Sa f’ ife Re ’yebiye fun mi.


2. Gbogb’ ohun ti mo ni, t’ ara t’ okan,

 Nko je fi du O, gba gbogbo re.


3. Sa ba mi gbe dopin, Oluwa mi,

 Jesu, Olugbala, Emmanuel.


4. B’ akoko Re ba de, je kin yin O;

 Yin O n’ ile Re titi lailai. Amin.



Yoruba Hymn  APA 213 - N’ iwaiya ’jakadi, On nikan nja


This is Yoruba Anglican hymns, APA 213- N’ iwaiya ’jakadi, On nikan nja  . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

إرسال تعليق (0)
أحدث أقدم