Yoruba Hymn APA 203 - E gb’ ohun ife at’ anu
APA 203
1. E gb’ ohun ife at’ anu,
Ti ndun l’ oke Kalfari!
Wo! o san awon apata!
O mi ’le, o m’ orun su
“O ti pari,” “O ti pari,”
Gbo b ’Olugbala ti ke.
2. “O ti pari!” b’ o ti dun to,
Ohun t’ oro wonyi wi,
Ibukun orun l’ ainiye
Ti odo Kristi san si wa;
“O ti pari,” “O ti pari,”
E ranti oro wonyi.
3. Ise igbala wa pari,
Jesu ti mu ofin se;
O pari, nkan t’ Olorun wi,
Awa ki o ka ’ku si;
“O ti pari,” “O ti pari,”
Elese, ipe l’ eyi.
4. E tun harpu nyin se, Seraf,
Lati korin ogo Re;
Ar’ aiye at’ ara orun,
Yin ’ruko Emmanuel;
“O ti pari!” “O ti pari”
Ogo fun Od’-agutan. Amin.
Yoruba Hymn APA 203 - E gb’ ohun ife at’ anu
This is Yoruba Anglican hymns, APA 203 - E gb’ ohun ife at’ anu . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals