Yoruba Hymn APA 182 - Are mu o, aiye su o
APA 182
1. Are mu o, aiye su o,
Lala po fun o ?
Jesu ni, “Wa si odo mi,
K’ o simi.”
2. Ami wo l’ emi o fi mo,
Pe On l’ o npe mi ?
Am’ iso wa lowo, ati
Ese Re.
3. O ha ni ade bi Oba,
Ti mo le fi mo ?
Toto, ade wa lori Re,
T’ egun ni.
4. Bi mo ba ri, bi mo tele,
Kini ere mi ?
Opolopo iya ati
’Banuje.
5. Bi mo tele tit’ aiye mi,
Kini ngo ri gba ?
Ekun a dopin, o simi,
Titi’ aiye
6. Bi mo bere pe, k’ O gba mi,
Y’o ko fun mi bi ?
B’ orun at’ aiye nkoja lo,
Ko je ko.
7. Bi mo ba ri, ti mo ntele,
Y’o ha bukun mi ?
Awon ogun orun nwipe,
Yio se. Amin.
Yoruba Hymn APA 182 - Are mu o, aiye su o
This is Yoruba Anglican hymns, APA 182- Are mu o, aiye su o . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.