Yoruba Hymn APA 138 - Ranse Olorun, e ma kede Re

Yoruba Hymn APA 138 - Ranse Olorun, e ma kede Re

Yoruba Hymn  APA 138 - Ranse Olorun, e ma kede Re

APA 138

 1. ’Ranse Olorun, e ma kede Re,

 E ma k’ okiki oruko Re nla;

 E gbe oruko Jesu asegun ga,

 Ijoba Re l’ ogo lor’ ohun gbogbo.


2. Olodumare, O njoba loke,

 O si sunmo wa, O mbe lodo wa;

 Ijo nla ni y’o korin isegun Re,

 O njewo pe, ti Jesu ni igbala.


3. Igbala ni t’ Olorun t’ o gunwa !

 Gbogb’ aiye kigbe, e f’ola f’Omo.

 Iyin Jesu ni gbogbo Angeli nke,

 N’idojubole, nwon nsin Odagutan.


4. E je k’awa sin, k’a f’ iyin Re fun,

 Ogo, agbara, ogbon at’ ipa,

 Ola at’ ibukun, pel’ awon Angel,

 Ope ti ko lopin at’ ife titi. Amin.

This is Yoruba Anglican hymns, APA 138-  Ranse Olorun, e ma kede Re  . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.

إرسال تعليق (0)
أحدث أقدم