Yoruba Hymn APA 137 - Wa jade larin Keferi p’ Oluwa l’ Oba
APA 137
1. Wa jade larin Keferi p’ Oluwa l’ Oba,
Wi jade ! Wi Jade !
Wi jade f’ orile-ede, mu ki nwon korin,
Wi jade ! Wi jade !
Wi jade tiyintiyin pe, On o ma po si,
Pe, Oba nla Ologo l’ Oba Alafia;
Wi jade tayotayo, bi iji tile nja,
Pe, O joko lor’ isan omi, Oba wa titi lai.
2. Wi jade larin Keferi pe, Jesu njoba,
Wi jade ! Wi Jade !
Wi jade f’ orile-ede, mu k’ ide won ja,
Wi jade ! Wi jade !
Wi jade fun awon ti nsokun, pe Jesu ye;
Wi jade f’ alare pe, O nfun ni nisimi;
Wi jade f’ elese pe, O wa lati gbala;
Wi jade fun awon ti nku pe, O ti segun iku.
3. Wi jade larin Keferi, Krist njoba loke,
Wi jade ! Wi jade !
Wi jade fun keferi, Ife n’ ijoba Re.
Wi jade ! Wi jade !
Wi jade lona opopo, l’ abuja ona,
Je k’o dun jakejado ni gbogbo agbaiye:
B’ iro omi pupo ni k’ iho ayo wa je,
titi gbohun-gbohun y’o fi gbe iron a de ’kangun aiye. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 137 - Wa jade larin Keferi p’ Oluwa l’ Oba . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.