Yoruba Hymn APA 129 - Olorun, gbogbo araiye

Yoruba Hymn APA 129 - Olorun, gbogbo araiye

Yoruba Hymn  APA 129 - Olorun, gbogbo araiye

APA 129

 1. Olorun, gbogbo araiye

 Ni eda owo Re;

 Ati ni ise Re t’ a nri

 Ogo didan Re ntan.


2. Sugbon ife nla Re ti ran

 Ihinrere s’ aiye;

 Ti nfi oro ore nla han,

 T’ o ti fi se ’sura.


3. ’Gbawo n’ ihin yi yio tan

 Yi gbogbo aiye ka,

 Ti gbogbo eya at’ okan

 Yio gbo iro na ?


4. ’Gbawo ni omo Afrika

 Y’o m’ adun oro na;

 At’ awon t’ o ti s’ eru pe,

 Yio di omnira ?


5. ’Gbawo ni awon keferi

 T’ o wa ni okunkun;

 Yio joko l’ ese Jesu,

 Lati ko ore Re ?


6. Oluwa bukun fun ise

 Itanka oro Re;

 K’ o si ko ’le iyin Re le

 Ite ese t’ o wo. Amin.

This is Yoruba Anglican hymns, APA 129 - Olorun, gbogbo araiye . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.

إرسال تعليق (0)
أحدث أقدم