Yoruba Hymn APA 123 - Baba orun ! emi fe wa

Yoruba Hymn APA 123 - Baba orun ! emi fe wa

 Yoruba Hymn  APA 123 - Baba orun ! emi fe wa

APA 123

1. Baba orun ! emi fe wa

 N’ iwa mimo, l’ ododo:

 Sugbon ife eran-ara

 Ntan mi je nigbagbogbo.


2. Ailalera ni emi se,

 Emi mi at’ ara mi;

 Ese ’gbagbogbo ti mo nda

 Wo mi l’ orun b’ eru nla.


3. Ofin kan mbe li okan mi

 ’Wo papa l’ o fi sibe;

 ’Tori eyi ni mo fi fe

 Tele ’fe at’ ase Re.


4. Sibe bi mo fe se rere,

 Lojukanna mo sina;

 Rere l’ oro Re i ma so;

 Buburu l’ emi sin se.


5. Nigba pupo ni mo njowo

 Ara mi fun idanwo:

 Bi a tile nkilo fun mi

 Lati gafara f’ ese.


6. Baba orun, Iwo nikan

 L’ o to lati gba mi la;

 Olugbala ti o ti ran,

 On na ni ngo gbamora.


7. Fi Emi Mimo Re to mi

 S’ ona titun ti mba gba;

 Ko mi, so mi, k’ o si to mi

 Iwo Emi Olorun. Amin.

This is Yoruba Anglican hymns, APA 123 -  Alakoso ti orun. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.

إرسال تعليق (0)
أحدث أقدم