Yoruba Hymn APA 121 - Olorun mi bojuwo mi

Yoruba Hymn APA 121 - Olorun mi bojuwo mi

 Yoruba Hymn  APA 121 - Olorun mi bojuwo mi

APA 121

1. Olorun mi bojuwo mi

 F’ iyanu ’fe nla Re han mi;

 Ma je ki ngbero fun’ ra mi,

 ’Tori ’Wo ni ngbero fun mi;

 Baba mi, to mi l’ aiye yi,

 Je ki ’gbala Re to fun mi.


2. Ma je ki mbu le O lowo,

 ’Tori ’Wo li onipin mi;

 S’ eyi ti ’Wo ti pinnu re,

 Iba je ponju tab’ ogo.

 Baba mi, &c.


3. Oluwa tal’ o ridi Re,

 Iwo Olorun ologo ?

 Iwo l’ egbegberun ona,

 Nibi ti nko ni ’kansoso.

 Baba mi, &c.


4. B’ orun ti ga ju aiye lo

 Beni ’ro Re ga ju t’ emi;

 Ma dari mi k’ emi le lo

 S’ ipa ona ododo Re.

 Baba mi, &c. Amin.

This is Yoruba Anglican hymns, APA 121-  Olorun mi bojuwo mi . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.

إرسال تعليق (0)
أحدث أقدم