Yoruba Hymn APA 113 - Irawo wo l’eyi
APA 113
1. Irawo wo l’eyi ?
Wo b’ o ti dara to,
Amona awon keferi
S’ odo Oba ogo.
2. Wo awon amoye
Ti ila-orun wa;
Nwon wa fi ori bale fun
Jesu Olubukun.
3. Imole ti Emi,
Ma sai tan n’ ilu wa;
Fi ona han wa k’ a le to,
Emmanueli wa.
4. Gbogbo irun-male,
Ati igba-male,
Ti a mbo n’ ile keferi,
K’ o yago fun Jesu.
5. Ki gbogbo Abore
Ti mbe ni Afrika,
Je amoye li otito,
Kin won gb’ ebo Jesu.
6. Baba Eleda wa,
Ti o fi Jesu han
Awon keferi igbani;
Fi han fun wa pelu. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 113 - Irawo wo l’eyi . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.