Yoruba Hymn 82 APA - Gba Jehofah da aiye
1. ’Gba Jehofah da aiye,
’Gbat’ o soro t’ o si se,
Awon Angeli nkorin
Halleluya gb’ orun kan.
2. Orin ’yin l’ a ko l’ oro
Gbat’ a bi Olugbala;
Orin ’yin ni a si ko
Nigbat’ o digbekun lo.
3. ’Gbat’ aiye y’o koja lo,
Iyin o gb’ ojo na kan;
’Gbat’ a o d’ aiye titun,
Orin iyin l’ a o ko.
4. Awa o ha dake bi
Titi joba na o de?
Beko ! Ijo o ma ko
Orin mimo at’ iyin.
5. Enia mimo l’ aiye,
Nf’ ayo korin iyin na;
Nipa ’gbagbo ni nwon nko,
Bi nwon o ti ko l’ oke.
6. Nigba emi o ba pin
Orin ni o segun ’ku;
Ninu ayo ailopin
Nwon o ma korin titi. Amin
This is Yoruba Anglican hymns, APA 82 - Gba Jehofah da aiye . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.