Yoruba Hymn APA 75 - Ji, ’wo Kristian, k’ o ki oro ayo

Yoruba Hymn APA 75 - Ji, ’wo Kristian, k’ o ki oro ayo

Yoruba Hymn APA 75-  Ji, ’wo Kristian, k’ o ki oro ayo

APA 75

 1. Ji, ’wo Kristian, k’ o ki oro ayo

 Ti a bi Olugbala araiye;

 Dide, k’ o korin ife Olorun,

 T’ awon Angeli nko n’ ijo kini.

 Lat’ odo won n’ ihin na ti bere;

 Ihin Om’ Olorun t’ a bi s’aiye.


2. ’Gbana l’ a ran akede Angeli,

 T’ o so f’ awon Olusagutan, pe,

 “ Mo mu ’hin rere Olugbala wa,

 T’ a bi fun nyin ati gbogbo aiye.

 Olorun mu ’leri Re se loni,

 A bi Olugbala Krist Oluwa.”


3. Bi akede Angel na ti so tan,

 Opolopo ogun orun si de;

 Nwon nkorin ayo t’ eti ko gbo ri,

 Orun si ho fun yin Olorun pe,

 “Ogo ni f’ Olorun l’ oke orun,

 Alafia at’ ife s’ enia.”


4. O ye k’ awa k’ o ma ro l’ okan wa,

 Ife nla t’ Olorun ni s’ araiye;

 T’ o wa jiya oro agbelebu.

 Ki awa si tele liana Re,

 Titi a o fi de ’bugbe l’ oke.


5. Nigbana ’gba ba de orun lohun,

 A o korin ayo t’ irapada;

 Y’o ma ran yi wa ka titi lailai;

 A o ma korin ife Re titi,

 Oba Angeli, Oba enia. Amin.

Yoruba Hymn APA 75-  Ji, ’wo Kristian, k’ o ki oro ayo

This is Yoruba Anglican hymns, APA 75 - Ji, ’wo Kristian, k’ o ki oro ayo . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.

إرسال تعليق (0)
أحدث أقدم