Yoruba Hymn APA 52 - Ijo ti nduro pe
APA 52
1. Ijo ti nduro pe
Lati ri Oluwa:
O si wa bakanna sibe
Ko s’alabaro fun !
Odun nyi lu odun,
Ojo ngori ojo,
Sibe lairi Oluwa re,
O wa ninu ofo:
Ma bo, Jesu, ma bo !
2. Awon mimo laiye
Opo won l’o ti ku
Bi nwon si tin lo l’okokan,
L’a nte won gbe ’ra won :
A te won lati sun
Ki se l’ainireti;
A te won lati reju ni
K’ile ogo to mo.
Ma bo, Jesu, Ma bo !
3. Awon ota npo si;
Agbara Esu nga;
Ogun ngbona, igbagbo nku,
Ife si di tutu.
Y’o tip e to ! Baba
Oloto, Olore !
’Wo ki y’o koya omije
At’ eje Ijo Re?
Ma bo, Jesu, ma bo.
4. A nfe gbo ohun Re,
A nfe f’oju kan O;
K’a le gba ade at’ogo
B’ a ti ngba ore Re.
Jo, wa m’ese kuro
At’ egun at’ eri,
K’o si so aiye osi yi
D’ aiye rere Tire
Ma bo, Jesu, ma bo. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 52 - Ijo ti nduro pe. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.