Yoruba Hymn APA 44 - A f’ope f’ Olorun
APA 44
1. A f’ope f’ Olorun,
L’ okan ati ohun wa,
Eni s’ ohun ’yanu,
N’nu Enit’ araiye nyo;
Gbat’ a wa l’om’ owo
On na l’o ntoju wa
O si nf’ ebun ife
Se ’toju wa sibe.
2. Oba Onib’ore
Ma fiwa sile lailai
Ayo ti ko lopin
On ’bukun y’o je tiwa;
Pa wa mo n’nu ore,
To wa gb’ a ba damu,
Yow a ninu ibi
Laiye ati l’orun.
3. K’ a f’ iyin on ope
F’ Olorun Baba, Omo,
Ati Emi Mimo;
Ti o ga julo l’orun,
Olorun kan lailai,
T’aiye at’orun mbo,
Be l’o wa d’isiyi,
Beni y’ o wa lailai. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 44 - A f’ope f’ Olorun. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.