Yoruba Hymn APA 96 - Baba ki m’ ya odun yi
APA 96
1. Baba ki m’ ya odun yi
Si mimo fun O,
N’ ipokipo ti o wu
Ti O fe ki nwa:
Bi ’banuje on ’rora
Nko gbodo komnu;
Eyi sa l’adura mi
“Ogo f’Oko Re.”
2. Om’owo ha le pase
’Biti on y’o gbe ?
Baba ’fe ha le du ni
L’ebun rere bi ?
’Jojumo n ’Iwo nfun wa
Ju bi o ti to,
O ko du wa l’ohun kan
T’y’o yin O logo.
3. Ninu anu, b’Iwo ba
Fun mi li ayo,
B’ Alafia on ’rora
Ba m’oju mi dan;
Gba okan mi ba nkorin,
Je k’o ma yin O,
Ohun t’ola ba mu wa
Ogo f’ Oko Re.
4. B’ O mu ’ponju wa ba mi,
T’ona mi sokun,
T’ere mi di adanu,
Ti ile mi kan;
Je ki nranti bi Jesu
Se d’Eni ogo,
Ki ngbadura n’nu ’ponju,
“Ogo f’Oko Re.” Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 96 - Baba ki m’ ya odun yi . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.