Yoruba Hymn APA 93 - Oluwa at’ igbala wa
APA 93
1. Oluwa at’ igbala wa,
Amona at’ agbara wa,
L’ o ko wa jo l’ ale oni,
Je k’ a gbe Ebeneser ro;
Odun t’ a ti la koja yi,
Ni on f’ ore Re de l’ ade,
Otun l’ anu Re l’ owuro;
Nje ki ope wa ma po si !
2. Jesu t’ o joko lor’ ite,
L’ a fi Halleluya wa fun;
Nitori Re nikansoso
L’ a da wa si lati korin;
Ran wa lowo lati kanu
Ese odun t’ o ti koja;
Fun ni k’ a lo eyi ti mbo,
S’ iyin Re, ju odun t’ o lo. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 93- Oluwa at’ igbala wa . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.