Yoruba Hymn APA 92 - Olorun, t’ odun t’ o koja
1. Olorun, t’ odun t’ o koja
Iret’ eyi ti mbo;
Ib’ isadi wa ni iji,
At’ ile wa lailai.
2. Labe ojiji ite Re
L’ awon enia Re ngbe !
Tito l’ apa Re nikanso,
Abo wa si daju.
3. K’ awon oke k’ o to duro,
Tabi k’ a to d’ aiye,
Lailai Iwo ni Olorun
Bakanna, l’ ailopin !
4. Egberun odun loju Re,
Bi ale kan l’ o ri;
B’ iso kan l’afemojumo,
Kio run k’o to la.
5. Ojo wa, bi odo sisan,
Opo l’ o si ngbe lo;
Nwon nlo, nwon di eni ’gbagbe,
Bi ala ti a nro.
6. Olorun t’ odun t’ o koja
Iret’ eyi ti mbo,
Ma s’ abo wa ’gba ’yonu de
At’ ile wa lailai. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 92 - Olorun, t’ odun t’ o koja . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.