Yoruba Hymn APA 86 - Onigbagbo, e bu sayo !
APA 86
1. Onigbagbo, e bu sayo !
Ojo nla l’ eyi fun wa;
K’ orun f’ ayo korin kikan,
K’ igbo at’ odan gberin.
E ho ! e yo ! E ho ! e yo !
Okun at’ odo gbogbo.
2. E jumo yo, gbogbo eda,
Laiye yi ati lorun;
Ki gbogbo ohun alaye
Nile loke yin Jesu.
E f’ ogo fun, E f’ ogo fun,
Oba nla t’ a bi loni !
3. Gb’ ohun nyin ga, “Omo Afrik”
Enyin iran Yoruba;
Ke ‘Hosanna !’ l’ ohun goro
Jake-jado ile wa.
K’ oba gbogbo, k’ oba gbogbo
Juba Jesu Oba wa.
4. E damuso ! e damuso !
E ho ye ! k’ e si ma yo:
Itegun esu fo wayi,
“Iru-omobinrin” de !
Halleluya ! Halleluya !
Olurapada, Oba.
5. Egb’ ohun nyin ga, Serafu,
Kerubu, leba ite;
Angeli at’ enyin mimo,
Pelu gbogbo’ ogun orun,
E ba way o ! E ba way o !
Odun idasile de.
6. Metalokan, Eni Mimo,
Baba, Olodumare,
Emi Mimo, Olutunu,
Jesu, Olurapada,
Gba iyin wa, Gba iyin wa,
’Wo nikan l’ ogo ye fun. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 86 - Onigbagbo, e bu sayo! . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.