Yoruba Hymn APA 588 - Gb’ adura wa, Oba aiye
APA 588
1. Gb’ adura wa, Oba aiye,
’Gbat’ a wole fun O;
Gbogbo wa nkigbe n’ irele,
A mbebe fun anu.
Tiwa l’ ebi, Tire l’ anu,
Mase le wa pada;
Sugbon gbo ’gbe wa n’ite Re,
Ran adura wa lowo.
2. Ese awon baba wa po,
Tiwa ko si kere;
Sugbon lati irandiran,
L’O ti f’ ore Re han.
Nigba ewu, b’omi jija,
Yi ilu wa yi ka,
Iwo l’a wo, t’a si kepe,
K’ a ma ri ranwo Re.
3. L’ ohun kan, gbogbo wa wole,
L’ abe ibawi Re;
Gbogbo wa njewo ese wa,
A ngbawe fun ’le wa.
F’ oju anu wo aini wa,
Bi a ti nkepe O;
Fi idajo Re ba wa wi,
Da wa si l’ anu Re. Amin.
Yoruba Hymn APA 588 - Gb’ adura wa, Oba aiye
This is Yoruba Anglican hymns, APA 588- Gb’ adura wa, Oba aiye. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals