Yoruba Hymn APA 564- L’oko Jesu, gbogbo ekun yio wole
APA 564
1. L’oko Jesu, gbogbo ekun yio wole,
Ahon yio jewo Re pe On l’Oba ogo;
Ife Bab nip e, k’a pe l’ Oluwa,
Enit’ ise Oro lat’ aiyeraye.
2. Nipa Oro re l’a da ohun gbogbo,
Awon angeli at’ awon imole,
Ite, ijoba, at’ awoon irawo,
Gbogbo eda orun ninu ogun won.
3. O re ‘ra Re sile, alti gb’ oruko,
Lodo awon elese t’o wa kun fun;
Ko je ki egan ba le oruko yi,
Titi O fi jjinde t’a si se l’ogo.
4. Oruko yi lo f’ayo gbe lo s’orun,
Koja gbogboe eda lo sibi giga,
S’ite Olorun, s’okan aiya Baba,
O si fi ogo isimi pipe kun.
5. F’ ife daruko Re, enyin ara, wa
Pelu eru jeeje ati iyanu,
Olorun Oluwa, Krist, Olugbala
Titi lao ma sin O, ao ma teriba.
6. E je ki Jesu joba n’nu okan nyin’
Y’o mu ohun buburu gbogbo kuro;
We l’ ogagun nyin l’a koko idanwo;
E je ki ‘fe Re je odi yi nyin ka.
7. Arakunrin, Jesu yi yio tun pada,
N’nu ogo Bab, pel’ awon angeli;
Gbogbo orile ede y’o wari fun,
Okan wa y’o jewo pe, On ni Oba. Amin.
Yoruba Hymn APA 564- L’oko Jesu, gbogbo ekun yio wole
This is Yoruba Anglican hymns, APA 564- L’oko Jesu, gbogbo ekun yio wole. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals