Yoruba Hymn APA 560 - E wole f’Oba, Ologo julo
APA 560
1. E wole f’Oba, Ologo julo
E korin ipa ati ife Re;
Alabo wa ni at’ Eni Igbani
O ngbe ‘nu ogo, Eleru ni iyin.
2. E so t’ipa Re, e so t’ore Re;
‘Mole l’ aso Re, kobi Re, orun
Ara ti nsan ni keke ‘binu Re je;
Ipa ona Re ni a ko si le mo.
3. Aiye yi pelu ekun ‘yanu re
Olorun agbara Re l’o da won;
O fi idi re mule, ko si le yi,
O si f’ okun se aso igunwa Re.
4. Enu ha le so ti itoju Re?
Ninu afefe, ninu imole;
Itoju Re wa nin’ odo t’o nsan,
O si wa ninu iri ati ojo.
5. Awa erupe, aw’ alailera
‘Wo l’a gbekele, O ki o da ni;
Anu Re ronu, o si le de opin,
Eleda, Alabo, Olugbala wa.
6. ‘Wo Alagbara, Onife Julo,
B’awon angeli ti nyin O l’oke,
Be l’awa eda Re, niwon t’a le se,
A o ma juba Re, a o ma yin O. Amin.
Yoruba Hymn APA 560 - E wole f’Oba, Ologo julo
This is Yoruba Anglican hymns, APA 560- E wole f’Oba, Ologo julo. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals