Yoruba Hymn APA 524 - Ibukun ni f’oku
APA 524
1. Ibukun ni f’oku,
T’o simi le Jesu;
Awon t’o gb’ ori won
Le okan aiya Re.
2. Iran ’bukun l’eyi,
Ko si ’boju larin;
Nwon ri En’ Imole,
Ti nwon ti fe lairi.
3. Nwon bo lowo aiye,
Pelu aniyan re;
Nwon bo lowo ewu,
T’o nrin l’ osan, l’oru.
4. Lori iboji won,
L’awa nsokun loni,
Nwon j’ en’ ire fun wa,
T’ a ki y’o gbagbe lai.
5. A k’yo gbohun won mo,
Ohun ife didun;
Lat’ oni lo, aiye
Ki o tun mo won mo.
6. Enyin oninure,
E fi wa sile lo;
Ao sokun nyin titi,
Jesu pa sokun ri.
7. Sugbon a fe gbohun
Olodumare na;
Y’o ko, y’o si wipe,
E dide, e si yo. Amin.
Yoruba Hymn APA 524 - Ibukun ni f’oku
This is Yoruba Anglican hymns, APA 524- Ibukun ni f’oku. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals