Yoruba Hymn APA 518 - Lala alagbase tan
APA 518
1. Lala alagbase tan;
Ojo ogun ti pari;
L’ ebute jijin rere
Ni oko re ti gun si:
Baba, labe itoju Re,
L’ awa f’ iranse Re yi si.
2. Nibe l’a re won l’ekun;
Nibe, nwon m’ ohun gbogbo;
Nibe l’ Onidaj’ oto
Ndan ise aiye won wo.
Baba, labe, &c.
3. Nibe l’ olus’ agutan
Nko awon agutan lo;
Nibe l’ o ndabobo won,
Koriko ko le de ’be.
Baba, labe, &c.
4. Nibe l’ awon elese,
Ti nteju m’ agbelebu,
Y’o mo ife Kristi tan,
L’ese Re ni Paradis.
Baba, labe, &c.
5. Nibe l’ agbara Esu
Ko le b’ ayo won je mo;
Kristi Jesu sa nso won,
On t’ o ku fun ’dande won.
Baba, labe, &c.
6. “Erupe fun erupe,”
L’ ede wa nisisiyi;
A te sile lati sun
Titi d’ojo ajinde.
Baba, labe, &c. Amin.
Yoruba Hymn APA 518 - Lala alagbase tan
This is Yoruba Anglican hymns, APA 518- Lala alagbase tan . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals