Yoruba Hymn APA 499 - Tire titi lai l’ awa se
APA 499
1. Tire titi lai l’ awa se,
Oluwa wa orun;
K’ ohun at’ okan wa wipe,
Amin, beni k’ o ri.
2. ‘Gbati aiye ban dun mo ni,
T’ o si nfa okan wa;
K’ iro yip e, “Tire l’ awa,”
Le ma dun l’ eti wa.
3. ‘Gbat’ ese pelu etan re,
Ba fe se wa n’ ibi;
K’iro yi pe, “Tire l’awa,”
Tu etan ese ka.
4. ‘Gbati Esu ba ntafa re,
S’ ori ailera wa;
K’iro yi pe, “Tire l’ awa,”
Ma je ki o re wa.
5. “Tire”, n’ igb’ a wa l’omode,
“Tire,” n’ igb’ a ndagba,
“Tire,” n’ igba’ a ba darugbo,
Ti aiye wa mbuse.
6. “Tire,” titi lai l’ awa se,
A f’ ara wa fun O:
Titi aiye anipekun,
Amin, beni k’o ri. Amin.
Yoruba Hymn APA 499 - Tire titi lai l’ awa se
This is Yoruba Anglican hymns, APA 499- Tire titi lai l’ awa se. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals