Yoruba Hymn APA 498 - Mo ti seleri, Jesu

Yoruba Hymn APA 498 - Mo ti seleri, Jesu

 Yoruba Hymn  APA 498 - Mo ti seleri, Jesu

APA 498

1. Mo ti seleri, Jesu,

 Lati sin O dopin;

 Ma wa lodo mi titi,

 Baba mi, Ore mi.

 Emi k’ yo beru ogun,

 B’ iwo ba sunmo mi,

 Emi ki y’o si sina,

 B’ o ba f’ona han mi.


2. Je ki mmo p’ o sunmo mi,

 ‘Tor’ ibaje aiye;

 Aiye fe gba okan mi,

 Aiye fe tan mi je;

 Ota yi mi ka kiri,

 Lode ati ninu’

 Sugbon Jesu, sunmo mi,

 Dabobo okan mi.


3. Je ki emi k’ o ma gbo

 Oun Re, Jesu mi,

 Ninu igbi aiye yi,

 Titi nigbagbogbo;

 So, mu k’ o da mi l’oju,

 K’ okan mi ni ‘janu;

 So, si mu mi gbo Tire,

 ‘Wo olutoju mi.


4. ‘Wo ti se ‘leri, Jesu,

 F’ awon t’ o tele O,

 Pe ibikibi t’ O wa,

 L’ awon yio si wa;

 Mo ti se ‘leri, Jesu,

 Lati sin O dopin.

 Je kin ma to O lehin,

 Baba mi, Ore mi.


5. Je kin ma ri ‘pase Re,

 Ki nle ma tele O:

 Agbara Re nikan ni,

 Ti mba le tele O.

 To mi, pe mi, si fa mi,

 Di mi mu de opin;

 Si gba mi si odo Re,

 Baba mi, Ore mi. Amin.



 Yoruba Hymn  APA 498 - Mo ti seleri, Jesu

This is Yoruba Anglican hymns, APA 498- Mo ti seleri, Jesu. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post