Yoruba Hymn APA 496 - Oluwa, k’ a ha w’ odo Re
APA 496
1. Oluwa, k’ a ha w’ odo Re?
Ebun orun ni a ntoro;
Nigba ti a wa ni ewe,
L’a ti gbe wa wa odo Re,
Fun wa ni ore-ofe Re,
K’ a le to O wa fun ’ra wa.
2. Oluwa, k’ a ha w’ odo Re,
Nigb’ a ba te tabili Re,
T’ a nse apere iku Re,
Ni jij’ akara, mimu wain?
Gb’ adura awon omo Re,
Kin won k’o le ri O nibe.
3. Oluwa, k’ a ha w’ odo Re,?
Ki se nigba yi nikan ni,
Sugbon ni gbogbo ojo wa,
Nigba oro tabi ise
K’a wa s’ idi ’te or’ofe,
K’ a duro sinsin n’ igbagbo.
4. Oluwa, k’ a ha w’ odo Re?
A fe, bere ebun kan si;
Pe, ’gbari aiye ba koja,
Ti ipe ikehin ba dun,
K’ a le w’ odo Re, Oluwa,
K’ a si nipo wa l’ aiya Re. Amin.
Yoruba Hymn APA 496 - Oluwa, k’ a ha w’ odo Re
This is Yoruba Anglican hymns, APA 496- Oluwa, k’ a ha w’ odo Re . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals