Yoruba Hymn APA 444 - K’ On to de, - je k’oro yi
APA 444
1. ‘K’ On to de, - je k’oro yi
Ma dun titi l’eti re;
Je ki sa die t’o ku
Han gbangba daju fun o;
Ronu b’orun on ile
Ti d’ ehin gbat’ O ba de.’
2. Gbat’ awon ti a feran
Bo si ‘simi won l’oke,
T’o jo pe aiye wa pin,
Ti adun re si koro;
E dakun, e ma b’ohun,
Kiki ‘k’ On to de’ sa ni.
3. Ibanuje yi wa ka;
A ha fe k’o dinku bi?
Gbogbo of aiye yi,
Iku, ofo on ‘boji
Nso jeje pe, ‘K’ On t’o de.
4. Wo tabil’ ife t’a te,
Mu waini, si j’akara;
‘Ranti didun, - k’ Oluwa
To pew a s’ onje orun;
‘Mi lat’ aiye, ‘mi l’orun,
Nwon pinya tit’ On fi de.’ Amin.
Yoruba Hymn APA 444 - K’ On to de, - je k’oro yi
This is Yoruba Anglican hymns, APA 444- K’ On to de, - je k’oro yi. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals