Yoruba Hymn APA 441 - Tal’ awa ba ha to lo

Yoruba Hymn APA 441 - Tal’ awa ba ha to lo

 Yoruba Hymn  APA 441 - Tal’ awa ba ha to lo

APA 441

1. Tal’ awa ba ha to lo,

 Bikos’ odo Re Jesu?

 ’Wo ti se imole wa,

 At’ iye ainipekun.

 Emi Re ti l’ owo to,

 T’ Emi Mimo nmi si wa?

 Onje Re atorunwa

 Li okan atunbi nfe.


2. Israeli l’ atijo,

 Nwon je manna, nwon si ku;

 Awon t’ o je l’ ara Re,

 Nwon ki y’o kebi lailai.

 Tal’ awa ba ha to lo,

 ’Gbat’ ibi ba yi wa ka?

 Bikos’ odo Re Jesu,

 ’Wo t’ ise iranwo wa.


3. Tal’ o le we okan wa,

 T’ o si le gbo igbe wa?

 Tani le kun okan wa,

 Olugbala, lehin Re?

 Iyin at’ ope ni fun O

 Titi, ’Wo Olorun mi;

 Ninu Re l’ em’ o ma wa,

 Ma wa ninu mi titi. Amin.



Yoruba Hymn  APA 441 - Tal’ awa ba ha to lo

This is Yoruba Anglican hymns, APA 441- Tal’ awa ba ha to lo. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post