Yoruba Hymn APA 439 - Ase ife orun
APA 439
1. Ase ife orun,
Ore-ofe l’o je
K’a je akara, k’a mu wain,
Ni ‘ranti Re Jesu.
2. Oluwa, a nduro,
Lati ko eko na;
T’ ohun ti mbe l’aiya Baba,
At’ ore-ofe Re.
3. Eri – okan ko to,
Igbagbo l’o fi han;
Pe, adun akara iye,
Ekun ife Re ni.
4. Eje tin san f’ese,
L’a r’apere re yi;
Eri si ni li okan wa,
Pe Iwo feran wa.
5. A! eri die yi,
Bi o ba dun bayi;
Y’o ti dun to l’oke orun,
Gbat’ a ba r’oju Re?
6. Lati ri oju Re,
Lati ri b’ O ti ri,
K’a si ma so ti ore Re
Titi aiyeraiye. Amin.
Yoruba Hymn APA 439 - Ase ife orun
This is Yoruba Anglican hymns, APA 439- Ase ife orun. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals