Yoruba Hymn APA 426 - Jesu, ba Ijo Re gbe
APA 426
1. Jesu, ba Ijo Re gbe,
Samona at’ odi re,
B’o ti nla ’danwo koja;
Awa mbe O, gbo tiwa.
2. F’ owo ife Re yi ka,
Dabobo lowo ota,
Tu ninu nigba ibi;
Awa mbe O, gbo tiwa.
3. M’ eko at’ iwa re mo;
Je k’o fi suru duro;
K’o simi le ’leri Re;
Awa mbe O, gbo tiwa.
4. Pelu re lojo gbogbo,
K’o bo lowo isina;
K’o ma sise fun yin Re;
Awa mbe O, gbo tiwa.
5. K’ ohun re ma ja goro,
N’ ikilo ’dajo ti mbo;
Ni siso ife Jesu:
Awa mbe O, gbo tiwa.
6. Wa tun ibaje re se,
Wa tun Tempili Re ko,
Fi ara Re han nibe,
Awa mbe O, gbo tiwa.
7. Wad a gbogbo ide re
Mu ’lara at’ ija tan,
M’ alafia orun wa,
Awa mbe O, gbo tiwa.
8. Mu gbogbo oran re to;
Ma je k’owo Esu te;
Ki aiye ma le tan je:
Awa mbe O, gbo tiwa.
9. K’ eko re je okanna,
N’nu otito at’ ife;
K’o fa opo s’ igbagbo
Awa mbe O, gbo tiwa.
10. K’o ma toju alaini,
K’o si ma wa asako,
At’ onirobinuje:
Awa mbe O, gbo tiwa.
11. Ma je k’ife re tutu,
M’ awon oluso gboiya,
S’ agbara y’ agbo Re ka:
Awa mbe O, gbo tiwa.
12. K’ awon alufa ma bo;
Kin won j’ oluso toto,
Lati ma to Ijo Re.
Awa mbe O, gbo tiwa.
13. Ki nwon se bi nwon ti nso,
K’ nwon f’apere mimo han
Bi asaju agbo Re,
Awa mbe O, gbo tiwa.
14. F’ or’-ofe Enit’ o ku
At’ ife Baba ba gbe;
K’ Emi ma samona re:
Awa mbe O, gbo tiwa.
15. We gbogbo arun re nu;
L’ eru on ’yemeji lo,
Mu ’segun re de Kankan.
Awa mbe O, gbo tiwa.
16. Ran lowo nigba awe,
Tit’ ise re o pari,
T’ Oko-yawo y’o si de:
Awa mbe O, gbo tiwa.
17. Nigbana k’O se logo,
Ati ni ailabawon,
L’ewa didan t’o ye O.
Awa mbe O, gbo tiwa.
18. Mu ye, ki on ba le pin
N’nu aye t’ Iwo npese;
Lai, k’o n’ ibukun nibe.
Awa mbe O, gbo tiwa.
Yoruba Hymn APA 426 - Jesu, ba Ijo Re gbe
This is Yoruba Anglican hymns, APA 426- Jesu, ba Ijo Re gbe . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals