Yoruba Hymn APA 425 - E wa k’ a da orin wa po
APA 425
1. E wa k’ a da orin wa po
Mo t’ awon Angeli;
Egbegberun ni ohun won,
Okan ni ayo won.
2. Nwon nkorin pe, “Ola nla ye
Odagutan t’ a pa:”
K’ a gberin pe, “Ola nla ye;”
’Tori O ku fun wa.
3. Jesu, li O ye lati gba,
Ola at’ agbara:
K’ iyin t’ enu wa ko le gba,
Je Tire, Oluwa.
4. K’ awon t’ o wa loke orun,
At’ ile, at’ okun;
Dapo lati gb’ ogo Re ga,
Jumo yin ola Re.
5. Ki gbogbo eda d’ ohun po,
Lati yin oruko
Enit’ o joko lor’ ite,
Kin won si wole fun. Amin.
Yoruba Hymn APA 425 - E wa k’ a da orin wa po
This is Yoruba Anglican hymns, APA 425- E wa k’ a da orin wa po . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals