Yoruba Hymn APA 416 - F’ awon enia Re t’ o lo ’simi

Yoruba Hymn APA 416 - F’ awon enia Re t’ o lo ’simi

Yoruba Hymn  APA 416 - F’ awon enia Re t’ o lo ’simi

APA 416

 1. F’ awon enia Re t’ o lo ’simi,

 Awon ti o f’ igbagbo jewo Re,

 K’a yin oruko Re, Olugbala,

 Alleluya!


2. Iwo l’ apata won at’ odi won,

 Iwo ni Balogun won l’oju ’ja,

 Iwo ni imole okunkun won.

 Alleluya!


3. Je ki awon omo-ogun Re l’aiye,

 Jagun nitoto b’awon ti ’gbani;

 Kin won le gba ade ogo bi won,

 Alleluya!


4. Idapo ibukun wo l’o to ’yi!

 Awa nja nihin, awon nyo lohun!

 Be Tire kanna l’awa at’ awon.

 Alleluya!


5. Gbat’ ija ba ngbona, ti ogun nle,

 A dabi eni ngb’ orin ayo won;

 Igboiya a si de, at’ agbara.

 Alleluya!


6. Ojo nlo, orun wa fere wo na,

 Awon ajagun toto y’o simi.

 Didun ni isimi Paradise,

 Alleluya!


7. Lehin eyi ojo ayo kan mbo,

 Awon mimo yo dide n’nu ogo;

 Oba ogo yio wa larin won.

 Alleluya!


8. Lat’ opin ile, lat’ opin okun,

 Ogunlogo nro wo ’bode pearli;

 Nwon nyin Baba, Omo, ati Emi.

 Alleluya! Amin.



Yoruba Hymn  APA 416 - F’ awon enia Re t’ o lo ’simi

This is Yoruba Anglican hymns, APA 416- F’ awon enia Re t’ o lo ’simi . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post