Yoruba Hymn APA 415 - Tal’ awon wonyi b’ irawo

Yoruba Hymn APA 415 - Tal’ awon wonyi b’ irawo

Yoruba Hymn  APA 415 - Tal’ awon wonyi b’ irawo

APA 415

 1. Tal’ awon wonyi b’ irawo,

 Niwaju ite mimo,

 Ti nwon si de ade wura,

 Egbe ogo wo l’eyi?

 Gbo! nwon nko Alleluya,

 Orin iyin Oba won!


2. Tali awon ti nko mana,

 T’ a wo l’ aso ododo?

 Awon ti aso funfun won

 Y’o ma funfun titi lai,

 Beni ki y’o gbo lailai:

 Nibo l’ egbe yi ti wa?


3. Awon wonyi l’ o ti jagun,

 F’ ola Olugbala won;

 Nwon jijakadi tit’ iku,

 Nwon ki b’ elese kegbe:

 Wonyi ni ko sa f’ ogun,

 Nwon segun nipa Kristi.


4. Wonyi l’ okan won ti gbogbe,

 Ninu danwo kikoro;

 Wonyi li o ti f’ adura,

 Mu Olorun gbo tiwon;

 Nisisiyi nwon segun,

 Olorun re won l’ekun.


5. Awon wonyi l’ o ti sora,

 Ti nwon fi ife won fun Kristi;

 Nwon si y’ ara won si mimo,

 Lati sin nigbagbogbo;

 Nisisiyi li orun,

 Nwon wa l’ ayo l’ odo Re. Amin.



Yoruba Hymn  APA 415 - Tal’ awon wonyi b’ irawo

This is Yoruba Anglican hymns, APA 415- Tal’ awon wonyi b’ irawo . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post