Yoruba Hymn APA 412 - Mura, elese, lati gbon

Yoruba Hymn APA 412 - Mura, elese, lati gbon

Yoruba Hymn  APA 412 - Mura, elese, lati gbon

APA 412 

 1. Mura, elese, lati gbon,

 Ma duro de ojo ola;

 Niwon b’ o ti kegan ogbon,

 Be l’ o si soro lati ri.


2. Mura lati bere anu,

 Ma duro de ojo ola;

 Ki igba re ko ma ba tan,

 Ki ojo ale yi to tan.


3. Mura, elese, k’ o pada,

 Ma duro de ojo ola;

 Nitori k’ egun ma ba o,

 K’ ojo ola k’ o to bere.


4. Mura lati gba ibukun,

 Ma duro de ojo ola;

 Ki fitila re ma ba ku,

 K’ ise rere re to bere.


5. Oluwa, y’elese pada,

 Ji kuro ninu were re;

 Ma je k’o tapa s’imo Re,

 K’o ma f’ egbe re se ’lora. Amin.



Yoruba Hymn  APA 412 - Mura, elese, lati gbon

This is Yoruba Anglican hymns, APA 412- Mura, elese, lati gbon . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post