Yoruba Hymn APA 335 - Jesu Oluwa, a fe O
APA 335
1. Jesu Oluwa, a fe O,
’Tori gbogbo ebun
Nt’ owo Re da lat’ oke wa,
B’ iri si gbogb’ aiye.
A yin O nitori wonyi;
K’ ise fun won nikan,
Ni awon omo-odo Re,
Se ngbadura si O.
2. Awa fe O, Olugbala,
’Tori ’gba t’ a sako;
Iwo pe okan wa pada,
Lati t’ ona iye.
’Gba t’ a wa ninu okunkun,
T’ a ri ninu ese:
’Wo ran imole Re si wa,
Lati f’ ona han wa.
3. Baba orun, awa fe O,
Nitori ’Wo fe wa;
’Wo ran Omo Re lati ku,
Ki awa le n’ iye.
’Gbat’ a wa labe binu Re
’Wo fun wa n’ ireti:
Bi ese t’ a da ti po to
Be l’ o dariji wa. Amin.
Yoruba Hymn APA 335 - Jesu Oluwa, a fe O
This is Yoruba Anglican hymns, APA 335- Jesu Oluwa, a fe O . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals