Yoruba Hymn APA 329 - Ngo feran Re, ‘wo odi mi

Yoruba Hymn APA 329 - Ngo feran Re, ‘wo odi mi

Yoruba Hymn  APA 329 - Ngo feran Re, ‘wo odi mi

APA 329

 1. Ngo feran Re, ‘wo odi mi;

 Ngo feran Re, wo ayo mi;

 Ngo feran Re, patapata,

 Ngo feran Re, tor’ ise Re,

 Ngo feran Re, tit’ okan mi,

 Y’o fi kun fun ife rere.


2. ‘Wo Orun mi, gba ope mi,

 Fun ‘mole Re t’o fi fun mi;

 Gba ope mi, ‘wo l’o gba mi

 Lowo awon ti nsota mi;

 Gba ope mi, fun ohun Re

 T’o mu mi yo lopolopo.


3. N’nu ire-ije mi laiye,

 Ma se alabojuto mi;

 Fi agbara fun ese mi,

 Ki nle t’ese m’ona rere;

 Ki mba le f’ipa mi gbogbo,

 F’ oruko Re t’o l’ogo han.


4. Ngo feran Re, ‘Wo ade mi,

 Ngo feran Re, Oluwa mi:

 Ngo feran Re nigbagbogbo,

 L’ojo ibi, l’ojo ire,

 Gbati ojo iku ba de,

 Ngo feran Re titi lailai. Amin.



Yoruba Hymn  APA 329 - Ngo feran Re, ‘wo odi mi

This is Yoruba Anglican hymns, APA 329-  Ngo feran Re, ‘wo odi mi   . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post