Yoruba Hymn APA 325 - Om’ Olorun a ko ri O
APA 325
1. Om’ Olorun a ko ri O,
’Gba t’ o wa s’ aiye iku yi;
Awa ko ri ibugbe Re,
Ni Nasareti ti a gan;
Sugbon a gbagbo p’ ese Re
Ti te ita re kakiri.
2. A ko ri O lori igi,
T’ enia buburu kan O mo:
A ko gbo igbe Re, wipe,
“Dariji won, tor’ aimo won.”
Sibe, a gbagbo pe, ’ku Re
Mi aiye, o si m’ orun su.
3. A ko duro leti boji,
Nibiti a gbe te O si;
A ko joko ’nu yara ni,
A ko ri O loju ona.
Sugbon a gbagbo p’ angeli
Wipe, “Iwo ti ji dide.”
4. A ko r’ awon wonni t’ o yan,
Lati ri ’goke-rorun Re;
Nwon ko fi iyanu woke,
Nwon si f’ eru dojubole.
Sugbon a gbagbo pen won ri O.
Bi O ti ngoke lo s’ orun.
5. Iwo njoba l’ oke loni,
’Wo si mbukun awon Tire;
Imole ogo Re ko tan
Si aginju aiye wa yi.
Sugbon, a gba oro Re gbo,
Jesu, Olurapada wa. Amin.
Yoruba Hymn APA 325 - Om’ Olorun a ko ri O
This is Yoruba Anglican hymns, APA 325- Om’ Olorun a ko ri O . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals