Yoruba Hymn APA 322 - Mo gbohun Jesu t’ o wipe

Yoruba Hymn APA 322 - Mo gbohun Jesu t’ o wipe

Yoruba Hymn  APA 322 - Mo gbohun Jesu t’ o wipe

APA 322

 1. Mo gbohun Jesu t’ o wipe,

 “Wa simi lodo Mi:

 Gbe ori re, wo alare,

 Le okan aiya Mi.”

 Nin’ are on ibinuje,

 Ni mo to Jesu wa,

 O je ib’ isimi fun mi,

 O si mu ’nu mi dun.


2. Mo gbohun Jesu t’ o wipe,

 “Iwo ti ongbe ngbe,

 Ngo f’ omi ’ye fun o lofe,

 Bere, mu, k’ o si ye.”

 Mo to Jesu wa, mo si mu

 Ninu omi ’ye na;

 Okan mi tutu, o soji,

 Mo d’ alaye n’nu Re.


3. Mo gbohun Jesu t’ o wipe,

 “ ’Mole aiye l’ Emi;

 Wo mi, Emi ni orun re,

 Ojo re y’o dara.”

 Mo wo Jesu, emi si ri,

 B’ Orun ododo mi.

 Ninu ’mole yi l’ em’ o rin,

 Tit’ ajo mi y’o pin. Amin.



Yoruba Hymn  APA 322 - Mo gbohun Jesu t’ o wipe

This is Yoruba Anglican hymns, APA 322-  Mo gbohun Jesu t’ o wipe  . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post