Yoruba Hymn APA 312 - N’ irumi at’ iji aiye
APA 312
1. N’ irumi at’ iji aiye,
Mo gbo ohun itunu kan,
O nso si mi l’eti wipe,
Emi ni; mase beru.
2. Emi l’o we okan re mo,
Emi l’o mu ki o riran,
Emi n’ iye, imole re,
Emi ni; mase beru.
3. Awon igbi omi wonyi
Ti f’ agbara won lu mi ri,
Nwon ko le se o n’ibi mo:
Emi ni; mase beru.
4. Mo ti mu ago yi lekan,
’Wo ko le mo kikoro re,
Emi ti mo bi o ti ri,
Emi ni; mase beru.
5. Mo pe, l’or’ eni arun re,
Oju Mi ko ye l’ara re,
Ibukun mi wa l’ori re,
“Emi ni : mase beru.”
6. Gbat’ emi re ba pin l’aiye,
T’ awon t’orun wa ’pade re,
’Wo o gbohun kan t’o mo, pe
“Emi ni: mase beru.” Amin .
Yoruba Hymn APA 312 - N’ irumi at’ iji aiye
This is Yoruba Anglican hymns, APA 312- N’ irumi at’ iji aiye . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals